Jeremiah 36:9 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ní oṣù kẹsan-an, ọdún karun-un tí Jehoiakimu ọmọ Josaya jọba ní Juda, gbogbo àwọn tí wọn ń gbé Jerusalẹmu ati àwọn eniyan tí wọ́n ti àwọn ìlú Juda wá sí Jerusalẹmu, kéde ọjọ́ ààwẹ̀ níwájú OLUWA.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣe li ọdun karun Jehoiakimu, ọmọ Josiah, ọba Juda, li oṣu kẹsan ni nwọn kede ãwẹ niwaju Oluwa, fun gbogbo enia ni Jerusalemu: ati fun gbogbo awọn enia ti o wá lati ilu Juda, si Jerusalemu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní oṣù kẹ́sàn-án ọdún karùn-ún Jéhóíákímù ọmọ Jòsáyà Ọba Júdà ni wọ́n kéde ààwẹ̀ níwájú OLÚWA fún gbogbo ènìyàn Jérúsálẹ́mù àti fún gbogbo àwọn ènìyàn tí ó wá láti Júdà.