Jeremiah 37:10 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Bí àwọn ará Juda bá tilẹ̀ ṣẹgun gbogbo ọmọ ogun àwọn ará Kalidea, tí wọ́n gbógun tì wọ́n, títí tí ó fi jẹ́ pé àwọn tí wọ́n ti fara gbọgbẹ́ nìkan ni wọ́n kù ninu àgọ́ wọn, wọn yóo dìde sí àwọn ará Juda, wọn yóo sì sun ìlú yìí níná.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori bi o tilẹ jẹ pe, ẹnyin lu gbogbo ogun awọn ara Kaldea ti mba nyin jà bolẹ, ti o si jẹ pe awọn ọkunrin ti o gbọgbẹ li o kù ninu wọn: sibẹ nwọn o dide, olukuluku ninu agọ rẹ̀, nwọn o si fi iná kun ilu yi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kódà tó bá ṣe pé wọn yóò ṣẹ́gun àwọn ọmọ ogun Bábílónì tí ń gbógun tì yín àti àwọn tí ìjàǹbá ṣe, tí wọ́n ti fi sílẹ̀ ní ibùdó wọn; wọn yóò jáde láti jó ìlú náà kanlẹ̀.”