Jeremiah 37:13 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Bí Jeremaya wolii ti dé bodè Bẹnjamini ọ̀kan ninu àwọn oníbodè tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Irija ọmọ Ṣelemaya ọmọ Hananaya mú un, ó ní, “O fẹ́ sálọ bá àwọn ará Kalidea ni.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati o si wà li ẹnu-bode Benjamini, balogun iṣọ kan wà nibẹ, orukọ ẹniti ijẹ Irijah, ọmọ Ṣelemiah, ọmọ Hananiah; on si mu Jeremiah woli, wipe, Iwọ nsa tọ̀ awọn ara Kaldea lọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n dé ẹnu-bodè Bẹ́ńjámínì, olórí àwọn olùṣọ́ tí orúkọ rẹ ń jẹ́ Íríjà ọmọ Ṣelemáyà ọmọ Hananáyà mú un, ó wí pé, “Ìwọ ń yapa sí àwọn ará Bábílónì.”