Jeremiah 37:17 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Sedekaya ọba ranṣẹ lọ mú un wá sí ààfin rẹ̀, ó sì fi ọ̀rọ̀ wá a lẹ́nu wò níkọ̀kọ̀, ó ní, “Ǹjẹ́ OLUWA ranṣẹ kankan?” Jeremaya dáhùn, ó ní, “Bẹ́ẹ̀ ni, ohun tí OLUWA sọ ni pé, a óo fi ọ́ lé ọba Babiloni lọ́wọ́.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni Sedekiah, ọba ranṣẹ pè e: ọba si bere lọwọ rẹ̀ nikọkọ ni ile rẹ̀, o si wipe, Ọ̀rọ ha wà lati ọdọ Oluwa? Jeremiah si wipe, O wà: o wi pe, nitori a o fi ọ le ọwọ ọba Babeli.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni Ọba Sedekáyà ránṣẹ́ sí i, tí ó sì pàṣẹ pé kí wọ́n mú wá sí ààfin níbi tí ó ti bi í ní ìkọ̀kọ̀ pé, “Ìfẹ́ ọ̀rọ̀ kan wà láti ọ̀dọ̀ OLÚWA?” “Bẹ́ẹ̀ ni,” Jeremáyà fèsì pé, “wọn ó fi ọ́ lé ọwọ́ Ọba Bábílónì.”