Jeremiah 37:21 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Sedekaya ọba bá pàṣẹ, wọ́n sì fi Jeremaya sinu gbọ̀ngàn ọgbà àwọn tí ń ṣọ́ ààfin. Wọ́n sì ń fún un ní burẹdi kan lojumọ láti òpópónà àwọn oníburẹdi títí tí gbogbo burẹdi fi tán ní ìlú. Bẹ́ẹ̀ ni Jeremaya ṣe bẹ̀rẹ̀ sí gbé gbọ̀ngàn àwọn tí ń ṣọ́ ààfin.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Sedekiah, ọba, si paṣẹ pe ki nwọn ki o fi Jeremiah pamọ sinu agbala ile-túbu, ati pe ki nwọn ki o ma fun u ni iṣu akara kọ̃kan lojojumọ, lati ita awọn alakara, titi gbogbo akara fi tan ni ilu. Jeremiah si wà li agbala ile-túbu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọba Sedekáyà wá pàṣẹ pé kí wọ́n fi Jeremáyà sínú àgbàlá àwọn ẹ̀ṣọ́, àti kí wọn sì fún ní àkàrà ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan títí tí àkàrà yóò fi tán; bẹ́ẹ̀ ni Jeremáyà wà nínú àgbàlá náà.