Jeremiah 37:7 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
OLUWA Ọlọrun Israẹli ní kí òun Jeremaya sọ fún ọba pé, àwọn ọmọ ogun Farao tí wọn wá ràn wọ́n lọ́wọ́ ti ń múra láti pada sí Ijipti, ilẹ̀ wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bayi li Oluwa, Ọlọrun Israeli wi pe, Bayi li ẹnyin o sọ fun ọba Juda, ti o rán nyin si mi, lati bere lọwọ mi: Wò o, ogun Farao ti o jade lati ràn nyin lọwọ, yio pada si ilẹ rẹ̀, ani Egipti.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Èyí ni, ohun tí OLÚWA Ọlọ́run àwọn Ísírẹ́lì sọ fún Ọba àwọn Júdà tó rán ọ láti wádìí nípa mi. ‘Àwọn ọmọ ogun Fáráò tó jáde láti kún ọ lọ́wọ́ yóò padà sílẹ̀ wọn sí Éjíbítì.