Jeremiah 37:9 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
OLUWA ní kí wọn sọ fún Sedekaya ati àwọn ará Juda kí wọn má tan ara wọn jẹ, kí wọn má sì rò pé àwọn ará Kalidea kò ní pada wá sọ́dọ̀ wọn mọ́, nítorí wọn kò ní lọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bayi li Oluwa wi; Ẹ máṣe tan ọkàn nyin jẹ, wipe, Ni lilọ awọn ara Kaldea yio lọ kuro lọdọ wa: nitoriti nwọn kì yio lọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Èyí ni ohun tí Ọlọ́run wí: Ẹ má ṣe tan ara yín jẹ ní èrò wí pé, ‘Àwọn ará Bábílónì yóò fi wá sílẹ̀ pẹ̀lú ìdánilójú;’ wọn kò ní ṣe bẹ́ẹ̀.