Jeremiah 38:14 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Sedekaya ọba ranṣẹ lọ mú Jeremaya wolii wá sọ́dọ̀ rẹ̀ ní ẹnu ọ̀nà kẹta tí ó wà ní Tẹmpili OLUWA, ó wí fún Jeremaya pé, “Ọ̀rọ̀ kan ni mo fẹ́ bèèrè lọ́wọ́ rẹ, má sì fi ohunkohun pamọ́ fún mi.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni Sedekiah, ọba, ranṣẹ, o mu Jeremiah woli, wá sọdọ rẹ̀ si ẹnu-ọ̀na kẹta ti o wà ni ile Oluwa: ọba si wi fun Jeremiah pe, Emi o bi ọ lere ohun kan: máṣe fi nkankan pamọ fun mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni Ọba Sedekáyà ránṣẹ́ pe, Jeremáyà òjíṣẹ́ Ọlọ́run àti láti mú un wá sí ẹnubodè kẹta nílé Ọlọ́run. Ọba sì sọ fún Jeremáyà pé, “Èmi yóò bi ọ́ ní ohun kan; má sì ṣe fi ohun kan pamọ́ fún mi.”