Jeremiah 38:16 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Sedekaya ọba bá búra fún Jeremaya ní ìkọ̀kọ̀ pé, “Mo fi OLUWA alààyè ẹni tí ó dá ẹ̀mí wa búra, pé n kò ní pa ọ́, n kò sì ní fi ọ́ lé àwọn tí wọn ń wá ọ̀nà láti pa ọ́ lọ́wọ́.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Sedekiah, ọba, si bura nikọkọ fun Jeremiah, wipe, Bi Oluwa ti wà, ẹni ti o da ẹmi wa yi, emi kì yio pa ọ, bẹ̃ni emi kì yio fi ọ le ọwọ awọn ọkunrin wọnyi, ti nwá ẹmi rẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n Ọba Sedekáyà búra ní ìkọ̀kọ̀ fún Jeremáyà wí pé, “Dájúdájú bí OLÚWA ti ń bẹ, ẹni tí ó fún wa ní ẹ̀mí, èmi kò ní pa ọ́ tàbí fà ọ́ fún àwọn tó ń lépa ẹ̀mí rẹ.”