Jeremiah 38:17 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Jeremaya bá wí fún Sedekaya pé, “OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní, bí o bá jọ̀wọ́ ara rẹ fún àwọn ìjòyè ọba Babiloni, wọn ó dá ẹ̀mí rẹ sí, wọn kò sì ní dáná sun ìlú yìí, ìwọ ati àwọn ará ilé rẹ yóo sì yè.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni Jeremiah sọ fun Sedekiah pe; Bayi li Oluwa Ọlọrun awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli, wi pe: Bi iwọ o ba jade nitõtọ tọ̀ awọn ijoye ọba Babeli lọ, nigbana ni ọkàn rẹ yio yè, a ki yio si fi iná kun ilu yi; iwọ o si yè ati ile rẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni Jeremáyà sọ fún Sedekáyà pé, “Èyí ni ohun tí OLÚWA Ọlọ́run alágbára, Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí: ‘Àyàfi bí o bá jọ̀wọ́ ara rẹ fún àwọn olóyè Ọba Bábílónì, a ó dá ẹ̀mí rẹ sí àti pé ìlú yìí kò ní di jíjó níná; ìwọ àti ilé rẹ yóò sì wà láàyè.