Jeremiah 38:18 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn bí o kò bá fi ara rẹ le àwọn ìjòyè ọba Babiloni lọ́wọ́, ìlú yìí yóo bọ́ sọ́wọ́ àwọn ará Kalidea, wọn yóo sì dáná sun ún, ìwọ pàápàá kò sì ní bọ́ lọ́wọ́ wọn.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn bi iwọ kì yio ba jade tọ awọn ijoye ọba Babeli lọ, nigbana ni a o fi ilu yi le ọwọ awọn ara Kaldea, nwọn o si fi iná kun u, iwọ kì yio si sala kuro li ọwọ wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n tí o kò bá jọ̀wọ́ ara rẹ fún àwọn ìjòyè Ọba Bábílónì, a ó fa ìlú yìí lé ọwọ́ àwọn Bábílónì. Wọn yóò sì fi ina sun-un, ìwọ gan-an kò ní le sá mọ́ wọn lọ́wọ́.’ ”