Jeremiah 38:19 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Sedekaya ọba bá wí fún Jeremaya pé, “Ẹ̀rù àwọn ará Juda tí wọ́n sá lọ bá àwọn ará Kalidea ń bà mí. Wọ́n lè fà mí lé wọn lọ́wọ́, kí wọ́n sì fi mí ṣẹ̀sín.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Sedekiah ọba, si sọ fun Jeremiah pe, Ẹ̀ru awọn ara Juda ti o ya tọ awọn ara Kaldea mbà mi, ki nwọn ki o má ba fi mi le wọn lọwọ; nwọn a si fi mi ṣẹsin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọba Sedekáyà sọ fún Jeremáyà pé, “Mò ń bẹ̀rù àwọn Júù tó ti sálọ sí ilẹ̀ Bábílónì, nítorí pé àwọn ará Bábílónì lè fà mí lé wọn lọ́wọ́ láti fìyà jẹ mí.”