Jeremiah 38:2 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“OLUWA ní, ẹni tí ó bá dúró ní ìlú Jerusalẹmu yóo kú ikú idà, ìyàn ati àjàkálẹ̀ àrùn; ṣugbọn àwọn tí wọn bá jáde tọ àwọn ará Kalidea lọ yóo yè. Ó ní ọ̀rọ̀ wọn yóo dàbí ẹni tí ó ja àjàbọ́, ṣugbọn yóo wà láàyè.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bayi li Oluwa wi pe, ẹniti o ba joko ni ilu yi yio kú nipa idà, nipa ìyan, ati nipa àjakalẹ-àrun, ẹniti o ba si jade tọ̀ awọn ara Kaldea lọ yio yè; a o si fi ẹmi rẹ́ fun u bi ikogun, yio si yè.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Èyí ni ohun tí OLÚWA wí: ‘Ẹnikẹ́ni tó bá dúró nínú ìlú yìí yóò kú nípa idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-àrùn; ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tó bá lọ sí Bábílónì yóò yè; yóò sá àsálà, yóò sì yè.’