Jeremiah 38:22 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wò ó, mo rí i tí wọn ń kó àwọn obinrin tí wọ́n wà ní ààfin ọba Juda jáde lọ sọ́dọ̀ àwọn ìjòyè ọba Babiloni, wọ́n sì ń wí pé, ‘Àwọn ọ̀rẹ́ rẹ tí o fọkàn tán tàn ọ́, wọ́n sì ti ṣẹgun rẹ; nisinsinyii tí o rì sinu ẹrẹ̀, wọ́n pada lẹ́yìn rẹ.’
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Si wò o, gbogbo awọn obinrin ti o kù ni ile ọba Juda li a o mu tọ̀ awọn ijoye ọba Babeli lọ, awọn obinrin wọnyi yio si wipe, Awọn ọrẹ rẹ ti tàn ọ jẹ, nwọn si ti bori rẹ: ẹsẹ rẹ̀ rì sinu ẹrẹ̀ wayi, nwọn pa ẹhin dà.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gbogbo àwọn obìnrin tó kù ní ààfin Ọba Júdà ni wọn yóò kó jáde fún àwọn ìjòyè Ọba Bábílónì. Àwọn obìnrin náà yóò sì sọ fún ọ pé: “ ‘Àwọn ọ̀rẹ́ rẹ tàn ọ́ jẹ, wọ́n sì borí rẹ. Ẹsẹ̀ rẹ rì sínú orọ̀fọ̀; àwọn ọ̀rẹ́ rẹ ti fi ọ́ sílẹ̀.’