Jeremiah 38:4 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn ìjòyè náà bá sọ fún ọba pé, “Ẹ jẹ́ kí á pa ọkunrin yìí nítorí pé ó ń mú ìrẹ̀wẹ̀sì bá àwọn ọmọ ogun tí wọn kù láàrin ìlú, ati gbogbo àwọn eniyan nítorí irú ọ̀rọ̀ tí ó ń sọ fún wọn. Ọkunrin yìí kò fẹ́ alaafia àwọn eniyan wọnyi, àfi ìpalára wọn.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn ijoye si sọ fun ọba pe, Jẹ ki a pa ọkunrin yi: nitori bayi li o mu ọwọ awọn ologun ti o kù ni ilu yi rọ, pẹlu ọwọ gbogbo enia, ni sisọ iru ọ̀rọ bayi fun wọn: nitori ọkunrin yi kò wá alafia awọn enia yi, bikoṣe ibi wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni àwọn ìjòyè wí fún Ọba pé, “Ó yẹ kí a pa ọkùnrin yìí; ó ń kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá àwọn ọmọ ogun tó kù nínú ìlú pẹ̀lú gbogbo àwọn ènìyàn nípa ohun tí ó ń sọ fún wọn. Ọkùnrin yìí kò fẹ́ ire fún àwọn ènìyàn bí kò ṣe ìparun.”