Jeremiah 38:6 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wọ́n bá mú Jeremaya, wọ́n jù ú sinu kànga Malikaya, ọmọ ọba, tí ó wà ní gbọ̀ngàn àwọn tí wọn ń ṣọ́ ààfin. Wọ́n fi okùn sọ Jeremaya kalẹ̀ sinu kànga náà, kò sí omi ninu rẹ̀, àfi ẹrẹ̀ nìkan, Jeremaya sì rì sinu ẹrẹ̀ náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si mu Jeremiah, nwọn si sọ ọ sinu iho Malkiah ọmọ Hammeleki, ti o wà li agbala ile-túbu: nwọn fi okun sọ Jeremiah kalẹ sisalẹ. Omi kò si si ninu iho na, bikoṣe ẹrẹ̀: Jeremiah si rì sinu ẹrẹ̀ na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n gbé Jeremáyà sọ sínú àmù Málíkíà ọmọ Ọbakùnrin tó wà ní àgbàlá àwọn ẹ̀ṣọ́, wọ́n ju Jeremáyà sínú àmù pẹ̀lú okùn; kò sì sí omi níbẹ̀ àyàfi ẹrọ̀fọ̀ nìkan, Jeremáyà sì rì sínú ẹrọ̀fọ̀.