Jeremiah 38:9 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Kabiyesi, oluwa mi, gbogbo nǹkan tí àwọn eniyan wọnyi ṣe sí wolii Jeremaya kò dára. Inú kànga ni wọ́n jù ú sí, ebi ni yóo sì pa á sibẹ nítorí pé kò sí burẹdi ní ìlú mọ́.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Oluwa mi, ọba! awọn ọkunrin wọnyi ti ṣe ibi ni gbogbo eyi ti nwọn ti ṣe si Jeremiah woli pe, nwọn ti sọ ọ sinu iho; ebi yio si fẹrẹ pa a kú ni ibi ti o gbe wà: nitori onjẹ kò si mọ ni ilu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“OLÚWA mi Ọba, àwọn ènìyàn wọ̀nyí ti ṣe ohun búburú sí Jeremáyà òjíṣẹ́ Ọlọ́run. Wọ́n ti gbé e sọ sínú àmù níbi tí kò sí oúnjẹ kankan nínú ìlú mọ́.”