Jeremiah 39:16 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
kí ó lọ sọ fún Ebedimeleki ará Etiopia pé, OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní, “Wò ó, n óo mú ìpinnu ibi tí mo ṣe lórí ìlú yìí ṣẹ, lójú rẹ ni yóo sì ṣẹ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Lọ, ki o si sọ fun Ebedmeleki, ara Etiopia, wipe: Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli wi pe, wò o, emi o mu ọ̀rọ mi wá sori ilu yi fun ibi, kì isi ṣe fun rere; nwọn o si ṣẹ niwaju rẹ li ọjọ na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Lọ sọ fún Ebedimélékì ará Kúṣì, ‘Èyí ni ohun tí OLÚWA àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí: Èmi ṣetan láti mú ọ̀rọ̀ mi ṣẹ lórí ìlú yìí nípa àjálù kì í ṣe àlàáfíà. Ní àkókò náà ni yóò ṣẹ lójú rẹ.