Jeremiah 39:18 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí pé, dájúdájú n óo gbà ọ́ sílẹ̀, o ò ní kú ikú idà, ṣugbọn o óo sá àsálà, nítorí pé o gbẹ́kẹ̀lé mi.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori emi o gbà ọ là nitõtọ, iwọ kì o si ti ipa idà ṣubu, ṣugbọn ẹ̀mi rẹ yio jẹ bi ikogun fun ọ: nitoripe iwọ ti gbẹkẹ rẹ le mi, li Oluwa wi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi yóò gbà ọ́ là; o kò ní ṣubú láti ipa idà; ṣùgbọ́n ìwọ yóò sá àsálà fún ẹ̀mí rẹ, nítorí pé ìwọ ní ìgbàgbọ́ nínú mi, ni OLÚWA wí.’ ”