Jeremiah 39:4 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí Sedekaya ọba Juda ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ rí wọn, wọ́n sá. Wọ́n fòru bojú, wọ́n bá jáde ní ìlú; wọ́n gba ọ̀nà ọgbà ọba, ní ọ̀nà ibodè tí ó wà láàrin odi meji, wọ́n sì dojú kọ ọ̀nà Araba.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣe, nigbati Sedekiah, ọba Juda, ati gbogbo awọn ologun ri wọn, nigbana ni nwọn sá, nwọn si jade kuro ni ilu li oru, nwọn gba ọ̀na ọgbà ọba ati ẹnu-bode lãrin odi mejeji, nwọn si jade lọ li ọ̀na pẹtẹlẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí Sedekáyà Ọba Júdà àti àwọn ọmọ ogun rí wọn, wọ́n sá, wọ́n kúrò ní ìlú ní alẹ́, wọ́n gba ọ̀nà ọgbà Ọba lọ láàrin ẹnubodè pẹ̀lú odi méjì, wọ́n dojúkọ aginjù.