Jeremiah 39:5 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn àwọn ọmọ ogun Kalidea lé wọn, wọ́n bá Sedekaya ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jẹriko; wọ́n mú un lọ sí ọ̀dọ̀ Nebukadinesari ọba Babiloni ní Ribila ní ilẹ̀ Hamati, ó sì dá Sedekaya lẹ́jọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn ogun awọn ara Kaldea lepa wọn, nwọn si ba Sedekiah, ọba, ni pẹtẹlẹ Jeriko; nigbati nwọn si mu u, nwọn mu u goke wá sọdọ Nebukadnessari, ọba Babeli, ni Ribla ni ilẹ Hamati, nibiti o sọ̀rọ idajọ lori rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn ọmọ ogun Bábílónì lé wọn, wọ́n bá Sedekáyà láàrin ihà Jẹ́ríkò. Wọ́n mú un ní ìgbékùn, wọ́n sì mú u tọ Nebukadinésárì Ọba Bábílónì àti Rábílà ní ilẹ̀ Hámátì, níbi tí wọ́n ti ṣe ìdájọ́ rẹ̀.