Jeremiah 4:11 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
A óo wí fún àwọn eniyan yìí, ati àwọn ará Jerusalẹmu ní ìgbà náà pé afẹ́fẹ́ gbígbóná kan ń fẹ́ bọ̀ láti orí àwọn òkè, ninu pápá, ó ń fẹ́ bọ̀ sọ́dọ̀ àwọn eniyan mi; kì í ṣe afẹ́fẹ́ lásán tíí fẹ́ pàǹtí ati ìdọ̀tí dànù.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni a o wi fun awọn enia yi ati fun Jerusalemu pe, Ẹfũfu gbigbona lati ibi giga ni iju niha ọmọbinrin enia mi, kì iṣe lati fẹ, tabi lati fẹnù.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni a ó sọ fún Jérúsálẹ́mù àti àwọn ènìyàn pé, “Ẹ̀fúùfù líle láti aṣálẹ̀ fẹ́ lu àwọn ènìyàn mi, kì í ṣe láti sọ di mímọ́.