Jeremiah 4:2 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
tí ẹ bá ń búra pẹlu òtítọ́ pé, ‘Bí OLUWA ti wà láàyè,’ lórí ẹ̀tọ́ ati òdodo, àwọn orílẹ̀-èdè yòókù yóo máa fi orúkọ mi súre fún ara wọn, wọn yóo sì máa ṣògo ninu mi.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Iwọ o si bura pe, Oluwa mbẹ ni otitọ, ni idajọ, ati ni ododo; ati nipasẹ rẹ̀ ni gbogbo orilẹ-ède yio fi ibukun fun ara wọn, nwọn o si ṣe ogo ninu rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Tí ó bá jẹ́ lóòtọ́ àti òdodo ni ìwọ búra. Nítòótọ́ bí OLÚWA ti wà láàyè, nígbà náà ni orílẹ̀ èdè yóò di alábùkún fún nípaṣẹ̀ rẹ àti nínú rẹ̀ ni wọn yóò ṣògo.