Jeremiah 4:29 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí wọ́n gbọ́ ariwo àwọn ẹlẹ́ṣin ati ti àwọn tafàtafà, gbogbo ìlú sá jáde fún ààbò. Wọ́n sá wọ inú igbó lọ, wọ́n gun orí òkè lọ sinu pàlàpálá òkúta; gbogbo ìlú sì di ahoro.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Gbogbo ilu ni yio sá nitori ariwo awọn ẹlẹṣin ati awọn tafatafa; nwọn o sa lọ sinu igbo; nwọn o si gun ori oke okuta lọ, gbogbo ilu ni a o kọ̀ silẹ, ẹnikan kì yio gbe inu wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nípa ariwo àwọn ẹlẹ́ṣin àti àwọn tafàtafà gbogbo ìlú yóò sálọ. Ọ̀pọ̀ sálọ sínú igbó; ọ̀pọ̀ yóò sì gun orí àpáta lọ. Gbogbo ìlú náà sì di ahoro; kò sì sí ẹnìkan nínú rẹ̀.