Jeremiah 4:31 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí mo gbọ́ igbe kan, tí ó dàbí igbe obinrin tí ó ń rọbí, ó ń kérora bí aboyún tí ó ń rọbí alákọ̀ọ́bí. Mo gbọ́ igbe Jerusalẹmu tí ń pọ̀ọ̀kà ikú, tí ó na ọwọ́ rẹ̀ síta, tí ń ké pé, “Mo gbé! Mò ń kú lọ, lọ́wọ́ àwọn apànìyàn!”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori mo ti gbọ́ ohùn kan bi ti obinrin ti nrọbi, irora bi obinrin ti nbi akọbi ọmọ rẹ̀, ohùn ọmọbinrin Sioni ti npohùnrere ẹkun ara rẹ̀, ti o nnà ọwọ rẹ̀ wipe: Egbé ni fun mi nisisiyi nitori ãrẹ mu mi li ọkàn, nitori awọn apania.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Mo gbọ́ ìró kan bí i igbe obìnrin tó ń rọbí, tí ó ń rọbí, ìrora bí i abiyamọ ọmọbìnrin Síónì tí ń pohùnréré ẹkún ara rẹ̀. Tí ó na ọwọ́ rẹ̀ tí ó sì wí pé, “Kíyèsí i mo gbé, Nítorí a ti fi ẹ̀mí mi lé àwọn apani lọ́wọ́.”