Jeremiah 4:7 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Kinniun kan ti jáde lọ láti inú igbó tí ó wà; ọ̀kan ninu àwọn tí wọ́n máa ń run àwọn orílẹ̀-èdè ti gbéra; ó ti jáde kúrò ní ipò rẹ̀, láti sọ ilẹ̀ yín di ahoro. Yóo pa àwọn ìlú yín run, kò sì ní sí eniyan ninu wọn mọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Kiniun jade wá lati inu pantiri rẹ̀, ati olubajẹ awọn orilẹ-ède dide: o jade kuro ninu ipo rẹ̀ lati sọ ilẹ rẹ di ahoro; ati ilu rẹ di ofo, laini olugbe.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kìnnìún ti sá jáde láti inú ibùgbé rẹ̀, apanirun orílẹ̀ èdè sì ti jáde. Ó ti fi àyè rẹ̀ sílẹ̀ láti ba ilẹ̀ rẹ̀ jẹ́. Ìlú rẹ yóò di ahoro láìsí olùgbé.