Jeremiah 4:9 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
OLUWA ní, “Tó bá di ìgbà náà, ojora yóo mú ọba ati àwọn ìjòyè, àwọn alufaa yóo dààmú, ẹnu yóo ya àwọn wolii.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Yio si ṣe li ọjọ na, li Oluwa wi, ọkàn ọba yio nù, ati ọkàn awọn ijoye: awọn alufa yio si dãmu, hà yio si ṣe awọn woli.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ní ọjọ́ náà,” ni OLÚWA wí pé, “àwọn Ọba àti ìjòyè yóò pàdánù ẹ̀mí wọn, àwọn àlùfáà yóò wárìrì, àwọn wòlíì yóò sì fòyà.”