Jeremiah 40:1 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
OLUWA bá Jeremaya sọ̀rọ̀ lẹ́yìn tí Nebusaradani, olórí àwọn tí ń ṣọ́ ọba Babiloni, tú u sílẹ̀ ní Rama. Nebusaradani rí Jeremaya tí wọ́n fi ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ dè é, wọ́n sì kó o pọ̀ mọ́ àwọn tí wọn kó kúrò ní ìlú Jerusalẹmu ati ní ilẹ̀ Juda tí wọn ń kó lọ sí Babiloni.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọ̀RỌ ti o tọ̀ Jeremiah wá lati ọdọ Oluwa, lẹhin ti Nebusaradani, balogun iṣọ, ti ranṣẹ pè e lati Rama. Nitori nigbati o mu u, a fi ẹwọn dè e lãrin gbogbo awọn igbekun Jerusalemu ati Juda, ti a kó ni ìgbekun lọ si Babeli.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọ̀rọ̀ náà sì tọ Jeremáyà wá láti ọ̀dọ̀ OLÚWA lẹ́yìn tí Nebukadinésárì balógun àwọn ẹ̀ṣọ́ ti tú u sílẹ̀ ní Rámà. Ó rí Jeremáyà tí a fi ẹ̀wọ̀n dè láàrin gbogbo àwọn tí wọ́n mú ní Jérúsálẹ́mù àti Júdà. Wọ́n kó lọ sí ilẹ̀ àjèjì Bábílónì.