Jeremiah 40:10 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ní tèmi, Misipa ni n óo máa gbé kí n lè máa rí ààyè bá àwọn ará Kalidea tí wọn wá dótì wá sọ̀rọ̀. Ẹ̀yin ẹ máa kó ọtí, èso, ati òróró jọ sinu ìkòkò yín, kí ẹ sì máa gbé àwọn ìlú tí ẹ ti gbà.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi o ṣe ti emi, wò o, emi o ma gbe Mispa, lati sìn awọn ara Kaldea, ti yio tọ wa wá; ṣugbọn ẹnyin ẹ kó ọti-waini jọ, ati eso-igi, ati ororo, ki ẹ si fi sinu ohun-elo nyin, ki ẹ si gbe inu ilu nyin ti ẹnyin ti gbà.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi fúnra mi yóò dúró ní Mísípà láti ṣojú yín níwájú Bábílónì tí wọ́n tọ̀ wá wá. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ni yóò máa kórè ọtí wáìnì, èso igi àti òróró; kí ẹ sì kó wọn sí inú àpò àpamọ́ yín; kí ẹ̀yin sì máa gbé ní ilẹ̀ tí ẹ ti gbà.”