Jeremiah 40:11 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Bákan náà, nígbà tí gbogbo àwọn ará Juda tí wọn wà ní ilẹ̀ Moabu, ati àwọn tí wọn wà ní ilẹ̀ àwọn ará Amoni ati ti Edomu ati àwọn tí wọ́n wà ní gbogbo ilẹ̀ káàkiri gbọ́ pé ọba Babiloni dá àwọn eniyan díẹ̀ sí ní Juda, àtipé ó fi Gedalaya, ọmọ Ahikamu, ọmọ Ṣafani, ṣe gomina wọn,
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Pẹlupẹlu gbogbo awọn ara Juda, ti o wà ni Moabu, ati lãrin awọn ọmọ Ammoni, ati ni Edomu, ati awọn ti o wà ni gbogbo ilẹ wọnni gbọ́ pe, ọba Babeli ti fi iyokù silẹ fun Juda, ati pe o ti fi Gedaliah, ọmọ Ahikamu, ọmọ Ṣafani, ṣolori wọn;
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí gbogbo àwọn Júdà ní Móábù, Ámónì, Édómù àti gbogbo àwọn orílẹ̀ èdè gbọ́ pé Ọba Bábílónì ti fi ohun tó kù sílẹ̀ ní Júdà, àti pé ó ti yan Jedáláyà ọmọkùnrin Áhíkámù ọmọkùnrin Sáfánì gẹ́gẹ́ bí gómìnà lórí wọn.