Jeremiah 40:12 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
gbogbo àwọn ará Juda pada láti gbogbo ibi tí wọn sá lọ, wọ́n wá sí ilẹ̀ Juda, wọ́n lọ sí ọ̀dọ̀ Gedalaya ní Misipa, wọ́n sì kó ọtí ati èso jọ lọpọlọpọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Gbogbo awọn ara Juda si pada lati ibi gbogbo wá ni ibi ti a ti lé wọn si, nwọn si wá si ilẹ Juda sọdọ Gedaliah si Mispa, nwọn si kó ọti-waini ati eso igi jọ pupọpupọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gbogbo wọn padà wá sí ilẹ̀ Júdà sọ́dọ̀ Jedáláyà ní Mísípà láti orílẹ̀ èdè gbogbo tí a ti lé wọn sí. Wọ́n sì kórè ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọtí wáìnì àti èṣo igi.