Jeremiah 40:13 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Johanani ọmọ Karea ati gbogbo àwọn olórí ogun tí wọ́n wà ní ìgbèríko wá sọ́dọ̀ Gedalaya ní Misipa.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn Johanani, ọmọ Karea, ati gbogbo awọn olori ogun ti o wà li oko, tọ̀ Gedaliah wá si Mispa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Jóhánánì ọmọkùnrin ti Káréà àti gbogbo àwọn ọmọ ogun tí ó kù ní orílẹ̀ èdè sì tọ Jedáláyà wá ní Mísípà.