Jeremiah 40:14 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọ́n sọ fún un pé, “Ǹjẹ́ o mọ̀ pé Baalisi, ọba àwọn ọmọ Amoni ti rán Iṣimaeli, ọmọ Netanaya pé kí ó wá pa ọ́?” Ṣugbọn Gedalaya kò gbà wọ́n gbọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si wi fun u pe, Iwọ ha mọ̀ dajudaju pe: Baalisi, ọba awọn ọmọ Ammoni, ti ran Iṣmaeli, ọmọ Netaniah, lati pa ọ? Ṣugbọn Gedaliah, ọmọ Ahikamu, kò gbà wọn gbọ́.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n sì sọ fún un wí pé, “Ǹjẹ́ ìwọ ha mọ̀ pé Báálísì Ọba àwọn Ámónì ti rán Íṣímáẹ́lì ọmọkùnrin Netanáyà láti lọ mú ẹ̀mí rẹ?” Ṣùgbọ́n Jedáláyà ọmọkùnrin ti Áhíkámù kò gbà wọ́n gbọ́.