Jeremiah 40:15 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Johanani bá sọ fún Gedalaya ní ìkọ̀kọ̀ ní Misipa pé, “Jẹ́ kí n lọ pa Iṣimaeli ọmọ Netanaya, ẹnikẹ́ni kò sì ní mọ̀. Kí ló dé tí o óo jẹ́ kí ó pa ọ́, tí gbogbo Juda tí wọn kóra jọ sí ọ̀dọ̀ rẹ yóo sì túká; tí àwọn tí wọn ṣẹ́kù ninu àwọn eniyan Juda yóo sì ṣègbé?”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni Johanani, ọmọ Karea, si sọ nikọkọ fun Gedaliah ni Mispa pe, Jẹ ki emi lọ, mo bẹ ọ, emi o si pa Iṣmaeli, ọmọ Netaniah, ẹnikan kì yio si mọ̀: Ẽṣe ti on o fi pa ọ, ti gbogbo awọn ara Juda ti a kojọ tì ọ, yio tuka, ati iyokù Juda yio ṣegbe?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni Jóhánánì ọmọkùnrin Káréà sọ ní ìkọ̀kọ̀ fún Jedáláyà ní Mísípà pé, “Jẹ́ kí èmi lọ pa Íṣímáẹ́lì ọmọkùnrin Netanáyà, ẹnikẹ́ni kò sì ní mọ èyí. Kí ni ìdí rẹ̀ tí yóò ṣe mú ẹ̀mí rẹ, tí o sì ṣe fẹ́ mú àwọn Júù tí ó yí ọ ká túká, kí ìyókù Júdà sì parun?”