Jeremiah 40:4 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nisinsinyii, wò ó, mo tú ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ ọwọ́ rẹ sílẹ̀, bí o bá fẹ́ bá mi lọ sí Babiloni, máa bá mi kálọ, n óo tọ́jú rẹ dáradára; bí o kò bá sì fẹ́ lọ, dúró. Wò ó, gbogbo ilẹ̀ nìyí níwájú rẹ yìí, ibi tí o bá fẹ́ tí ó dára lójú rẹ ni kí o lọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Njẹ nisisiyi, wò o, mo tú ọ silẹ li oni kuro ninu ẹ̀wọn ti o wà li ọwọ rẹ: bi o ba dara li oju rẹ lati ba mi lọ si Babeli, kalọ, emi o boju to ọ: ṣugbọn bi kò ba dara li oju rẹ lati ba mi lọ si Babeli, jọwọ rẹ̀; wò o, gbogbo ilẹ li o wà niwaju rẹ, ibi ti o ba dara ti o ba si tọ li oju rẹ lati lọ, lọ sibẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n, ní òní yìí mò ń tú ọ sílẹ̀ kúrò nínú ẹ̀wọ̀n tí ó wà ní ọwọ́ rẹ. Bí o bá fẹ́, tẹ̀lémi kálọ sí Bábílónì, èmi yóò sì bojútó ọ; ṣùgbọ́n bí ìwọ kò bá fẹ́, má ṣe wá. Wò ó, gbogbo orílẹ̀ èdè wà níwájú rẹ, lọ sí ibikíbi tí ó bá tẹ́ ọ lọ́rùn.”