Jeremiah 40:5 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Bí o bá fẹ́ pada, pada lọ bá Gedalaya ọmọ Ahikamu, ọmọ Ṣafani, ẹni tí ọba Babiloni fi ṣe gomina àwọn ìlú Juda, kí o máa bá a gbé láàrin àwọn eniyan náà. Bí o kò bá sì fẹ́ bẹ́ẹ̀, ibi tí ó bá wù ọ́ láti lọ ni kí o lọ.” Olórí àwọn ẹ̀ṣọ́ ọba bá fún un ní owó, oúnjẹ, ati ẹ̀bùn, ó ní kí ó máa lọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi bẹ̃kọ, pada tọ̀ Gedaliah, ọmọ Ahikamu, ọmọ Ṣafani, ẹniti ọba Babeli ti fi jẹ bãlẹ lori ilu Juda, ki o si mã ba a gbe lãrin ọpọ enia, tabi ibikibi ti o ba tọ li oju rẹ, lati lọ, lọ sibẹ̀. Balogun iṣọ si fun u li onjẹ ati ẹbun; o si jọ́wọ́ rẹ̀ lọwọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹ̀wẹ̀, kí ó tó di pé Jeremáyà pẹ̀yìn dà láti máa lọ, Nebusárádánì fikún un wí pé, “Padà lọ sí ọ̀dọ̀ Jedaláyà ọmọ Álíkámù, ọmọ Sáfánì, ẹni tí Ọba Bábílónì ti yàn gẹ́gẹ́ bí olórí lórí ìlú Júdà, kí o sì máa gbé ní àárin àwọn ènìyàn wọ̀nyí tàbí kí o máa lọ ibikíbi tí ó bá wù ọ́.” Nígbà náà ni balógun náà fún un ní oúnjẹ àti ẹ̀bùn, ó sì jẹ́ kí ó lọ.