Jeremiah 40:7 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí gbogbo àwọn olórí ogun tí wọ́n wà ní ìgbèríko pẹlu àwọn ọmọ ogun wọn gbọ́ pé ọba Babiloni ti fi Gedalaya ọmọ Ahikamu jẹ gomina ní ilẹ̀ Juda, ati pé ó ti fi ṣe olùtọ́jú àwọn ọkunrin, ati àwọn obinrin, ati àwọn ọmọde ati díẹ̀ ninu àwọn talaka ilẹ̀ Juda, tí wọn kò kó lọ sí Babiloni,
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Njẹ nigbati gbogbo awọn olori ogun, ti o wà li oko, awọn ati awọn ọkunrin wọn, gbọ́ pe ọba Babeli ti fi Gedaliah, ọmọ Ahikamu, jẹ bãlẹ ni ilẹ na, o si ti fi awọn ọkunrin fun u, ati awọn obinrin, ati awọn ọmọde, ati ninu awọn talaka ilẹ na, ninu awọn ti a kò kó lọ ni igbekun si Babeli.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí gbogbo àwọn olórí ogun àti àwọn ènìyàn tí wọ́n kù lórí orílẹ̀ èdè náà gbọ́ pé Ọba Bábílónì ti yan Jedáláyà ọmọkùnrin Áhíkámù gẹ́gẹ́ bí gómìnà ní ilẹ̀ náà; àti pé ó ti fi àwọn ọkùnrin, obìnrin àti ọmọdé tí wọ́n jẹ́ talákà ní ilẹ̀ náà tí wọn kò kó lọ sí ilẹ̀ àjèjì sí ìkáwọ́ rẹ̀