Jeremiah 40:8 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
wọ́n lọ bá Gedalaya ní Misipa. Àwọn tí wọ́n lọ nìwọ̀nyí: Iṣimaeli, ọmọ Netanaya, Johanani, ọmọ Karea, Seraaya, ọmọ Tanhumeti, àwọn ọmọ Efai, ará Netofa, Jesanaya, ọmọ ará Maakati, àwọn àtàwọn eniyan wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn tọ̀ Gedaliah wá ni Mispa, ani Iṣmaeli, ọmọ Netaniah, ati Johanani, ati Jonatani, awọn ọmọ Karea, ati Seraiah, ọmọ Tanhumeti, ati awọn ọmọ Efai, ara Netofa, ati Jesaniah, ọmọ ara Maaka, awọn ati awọn ọkunrin wọn,
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n wá sí ọ̀dọ̀ Jedáláyà ní Mísípà, Íṣímáẹ́lì ọmọkùnrin Netanáyà, Jóhánónì àti Jónátanì ọmọkùnrin ti Káréà, Séráyà ọmọkùnrin Tánúmétì tí í ṣe ọmọkùnrin Épáì ti Nétópátè àti Jásáníà ọmọkùnrin Mákétè àti àwọn ènìyàn wọn.