Jeremiah 41:1 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ní oṣù keje ni Iṣimaeli, ọmọ Netanaya ọmọ Eliṣama dé, ìdílé ọba ni ó ti wá, ó sì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìjòyè ọba. Òun pẹlu àwọn ọkunrin mẹ́wàá bá lọ sọ́dọ̀ Gedalaya ọmọ Ahikamu ní Misipa. Bí wọ́n ṣe ń jẹun lọ́wọ́ ní Misipa,
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣe li oṣu keje Iṣmaeli, ọmọ Netaniah ọmọ Eliṣama, ninu iru-ọmọ ọba, ati awọn ijoye ọba, ati ọkunrin mẹwa pẹlu rẹ̀, nwọn tọ̀ Gedaliah, ọmọ Ahikamu, wá ni Mispa: nibẹ ni nwọn jumọ jẹun ni Mispa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní oṣù keje Íṣímáẹ́lì ọmọkùnrin Netanáyà, ọmọkùnrin Élísámà ti ìdílé Ọba, tí ó sì ti jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìjòyè Ọba, tọ Jedaláyà ọmọ Áhíkámù ti Mísípà wá pẹ̀lú ọkùnrin mẹ́wàá. Nígbà tí wọ́n ń jẹun papọ̀.