Jeremiah 41:10 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Iṣimaeli bá kó gbogbo àwọn tí wọ́n kù ní Misipa lẹ́rú, àwọn ọmọ ọba lobinrin ati gbogbo àwọn tí wọ́n kù ní Misipa, àwọn tí Nebusaradani olórí àwọn tí wọn ń ṣọ́ ọba fi sí abẹ́ ìṣọ́ Gedalaya. Iṣimaeli kó wọn lẹ́rú ó sì fẹ́ kó wọn kọjá sí ọ̀dọ̀ àwọn ará Amoni.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Iṣmaeli si kó gbogbo iyokù awọn enia ti o wà ni Mispa ni igbekun, awọn ọmọbinrin ọba, ati gbogbo enia ti o kù ni Mispa, awọn ti Nebusaradani, balogun iṣọ, ti fi le Gedaliah, ọmọ Ahikamu lọwọ: Iṣmaeli, ọmọ Netaniah, si kó wọn ni igbekun, o si kuro nibẹ lati rekọja lọ sọdọ awọn ọmọ Ammoni.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ísímáẹ́lì sì kó gbogbo àwọn ènìyàn tí ó wà ní Mísípà nígbèkùn, ọmọbìnrin Ọba àti gbogbo àwọn ènìyàn tó kù síbẹ̀ lórí àwọn tí Nebusarádánì balógun àwọn ẹ̀sọ́ ti fi yan Gédáláyà ọmọkùnrin Álíkámù ṣe olórí. Isímáẹ́lì ọmọkùnrin Nétanáyà kó wọn ní ìgbèkùn, ó sì jáde rékọjá sí ọ̀dọ̀ àwọn Ámónì.