Jeremiah 41:16 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Lẹ́yìn náà Johanani ọmọ Karea, ati gbogbo àwọn olórí ogun tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀, kó gbogbo àwọn tí Iṣimaeli ọmọ Netanaya kó lẹ́rú ní Misipa, lẹ́yìn tí ó pa Gedalaya ọmọ Ahikamu tán, ó bá kó ati àwọn ọmọ ogun, ati àwọn obinrin, ati àwọn ọmọde, ati àwọn ìwẹ̀fà, pada wá láti Gibeoni.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Johanani, ọmọ Karea, ati gbogbo awọn olori ogun ti o wà pẹlu rẹ̀, si mu gbogbo iyokù awọn enia ti o ti gbà lọwọ Iṣmaeli, ọmọ Netaniah, lati Mispa, lẹhin ti o ti pa Gedaliah, ọmọ Ahikamu ani, akọni ọkunrin ogun, ati awọn obinrin, ati awọn ọmọde, ati awọn iwẹfa, awọn ti o ti tun mu pada lati Gibeoni wá:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Lẹ́yìn náà Jóhánánì ọmọkùnrin Káréà àti gbogbo àwọn ọmọ ogun tí wọn wà pẹ̀lú rẹ̀ sì kó gbogbo àwọn tí ó kù ní Mísípà; àwọn tí ó ti rí gbà lọ́wọ́ Ísímáẹ́lì ọmọkùnrin Nétanáyà; lẹ́yìn ìgbà tí ó ti pa Gédáláyà ọmọ Álíkámù. Àwọn ọmọ ogun, àwọn obìnrin, àwọn ọmọdé àti àwọn olórí ilé ẹjọ́ tí ó ti kó wa láti Gíbíónì.