Jeremiah 41:2 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Iṣimaeli, ọmọ Netanaya ati àwọn mẹ́wàá tí wọ́n bá a wá dìde, wọ́n bá fi idà pa Gedalaya tí ọba Babiloni fi ṣe gomina ilẹ̀ náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni Iṣmaeli, ọmọ Netaniah, ati awọn ọkunrin mẹwa ti nwọn wà pẹlu rẹ̀, nwọn fi idà kọlu Gedaliah, ọmọ Ahikamu, ọmọ Ṣafani, nwọn si pa a, on ẹniti ọba Babeli ti fi jẹ bãlẹ lori ilẹ na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Íṣímáẹ́lì ọmọ Netanáyà àti àwọn ọkùnrin mẹ́wàá tí wọ́n wà pẹ̀lú rẹ̀, sì dìde wọ́n kọlu Jedaláyà ọmọ Áhíkámù, ọmọ Sáfánì pẹ̀lú idà. Wọ́n sì pa á, ẹni tí Ọba Bábílónì ti yàn gẹ́gẹ́ bí gómìnà lórí ilẹ̀ náà.