Jeremiah 41:5 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
àwọn ọgọrin eniyan kan wá láti Ṣekemu, Ṣilo ati láti Samaria pẹlu irùngbọ̀n wọn ní fífá, wọ́n fa agbádá wọn ya, wọ́n sì ṣá ara wọn lọ́gbẹ́. Wọ́n mú ọrẹ ẹbọ ati turari lọ́wọ́ wá sí Tẹmpili OLUWA.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni ọgọrin ọkunrin wá lati Ṣekemu, lati Ṣilo, ati lati Samaria, ti nwọn fá irungbọn wọn, nwọn fà aṣọ wọn ya, nwọn si ṣá ara wọn lọgbẹ, nwọn mu ọrẹ-ẹbọ ati turari li ọwọ wọn lati mu u wá si ile Oluwa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ọgọ́rin ọkùnrin wá láti Ṣékémù, Ṣílò àti Saaríà, wọ́n fa irùngbọ̀n wọn, wọ́n ya aṣọ wọn, wọ́n sá ara wọn lọ́gbẹ́ wọ́n mú ẹbọ ọpẹ́ àti tùràrí wá sí ilé OLÚWA.