Jeremiah 41:8 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn àwọn mẹ́wàá kan ninu wọn sọ fún Iṣimaeli pé, “Má pa wá, nítorí a ní ọkà wíítì, ọkà baali, ati òróró ati oyin ní ìpamọ́ ninu oko.” Nítorí náà, ó fi wọ́n sílẹ̀ kò sì pa wọ́n bí ó ti pa àwọn yòókù wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn ọkunrin mẹwa wà lãrin wọn ti nwọn sọ fun Iṣmaeli pe, máṣe pa wa: nitori awa ni iṣura li oko, ti alikama, ati ti ọka barli, ati ti ororo, ati oyin. Bẹ̃li o jọwọ wọn, kò si pa wọn pẹlu awọn arakunrin wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n mẹ́wàá nínú wọn sọ fún Ísímáẹ́lì pé, “Má se pa wá! Àwa ní ọkà àti Bálì, òróró àti oyin ní ìpamọ́ nínú oko.” Nítorí náà, ó fi wọ́n sílẹ̀: kò sì pa wọ́n pẹ̀lú àwọn yóòkù.