Jeremiah 41:9 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Kòtò tí Iṣimaeli ju òkú àwọn eniyan tí ó pa sí ni kòtò tí ọba Asa gbẹ́ tí ó fi dí ọ̀nà mọ́ Baaṣa ọba Israẹli; ṣugbọn Iṣimaeli, ọmọ Netanaya fi òkú eniyan tí ó pa kún kòtò náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati iho na ninu eyi ti Iṣmaeli ti sọ gbogbo okú ọkunrin wọnyi si, awọn ti o ti pa pẹlu Gedaliah, ni eyiti Asa, ọba, ti ṣe nitori ibẹ̀ru Baaṣa, ọba Israeli: Iṣmaeli, ọmọ Netaniah, si fi awọn ti a pa kún u.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nísinsìn yìí, ihò náà tí ó kó gbogbo ara àwọn ọkùnrin tí ó ti pa pẹ̀lú Jedaláyà sí ni Ọba Aṣa ń lò gẹ́gẹ́ bí i ààbò nítorí Ọba Báṣì ti Ísírẹ́lì. Ísímáẹ́lì ọmọ Nétanáyà sì ti kó òkú kún inú rẹ̀.