Jeremiah 42:11 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹ má bẹ̀rù ọba Babiloni tí ẹrù rẹ̀ ń bà yín, ẹ má bẹ̀rù rẹ̀; èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀, nítorí pé mo wà pẹlu yín. N óo gbà yín là n óo sì yọ yín lọ́wọ́ rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹ má bẹ̀ru ọba Babeli, ẹniti ẹnyin mbẹ̀ru: ẹ máṣe bẹ̀ru rẹ̀, li Oluwa wi: nitori emi wà pẹlu nyin lati ràn nyin lọwọ, ati lati gbà nyin li ọwọ rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹ má ṣe bẹ̀rù Ọba Bábílónì tí ẹ̀yin ń bẹ̀rù, báyìí ẹ má ṣe bẹ̀rù rẹ̀ ni OLÚWA wí; nítorí tí èmi wà pẹ̀lú yín láti pa yín mọ́ àti láti gbàyín ní ọwọ́ rẹ̀.