Jeremiah 42:15 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ OLUWA, ẹ̀yin tí ẹ ṣẹ́kù ní Juda. OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní, ‘Bí ẹ bá gbójú lé àtilọ sí Ijipti, pé ẹ óo lọ máa gbé ibẹ̀, ogun tí ẹ̀ ń sá fún yóo bá yín níbẹ̀;
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Njẹ nisisiyi, nitorina, ẹ gbọ́ ọ̀rọ Oluwa, ẹnyin iyokù Juda, Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli, wi pe, Bi ẹ ba gbe oju nyin patapata le ati lọ si Egipti, bi ẹnyin ba lọ lati ṣe atipo nibẹ,
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí náà, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ OLÚWA ẹ̀yin ìyókù Júdà èyí ni ohun tí OLÚWA Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun Ísírẹ́lì wí: ‘Bí ẹ̀yin bá pinnu láti lọ sí Éjíbítì láti lọ ṣe àtìpó ńibẹ̀.