Jeremiah 42:17 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Gbogbo àwọn tí wọ́n bá gbójú lé àtilọ sí Ijipti láti máa gbé ibẹ̀ yóo kú ikú ogun, ati ti ìyàn pẹlu àjàkálẹ̀ àrùn, wọn kò ní ṣẹ́kù, bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni wọn kò ní bọ́ ninu ibi tí n óo mú wá sórí wọn.’
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bẹ̃ni gbogbo awọn ọkunrin ti nwọn gbe oju wọn si ati lọ si Egipti lati ṣatipo nibẹ; nwọn o kú, nipa idà, nipa ìyan, tabi nipa àjakalẹ-arun, ẹnikẹni ninu wọn kì yio kù, tabi kì o sala kuro ninu ibi ti emi o mu wá sori wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí náà, gbogbo àwọn tí ó ti pinnu láti ṣe àtìpó ní Éjíbítì ni yóò ti ipa idà kú, ìyàn àti àjàkálẹ̀-àrùn kò sì ní jẹ́ kí ẹníkẹ́ni nínú wọn yè tàbí sá àsálà nínú ibi tí èmi yóò mú wá sórí wọn.’