Jeremiah 42:18 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní, ‘Bí mo ti bínú sí àwọn ará Jerusalẹmu, tí inú mi sì ń ru sí wọn, bẹ́ẹ̀ ni n óo bínú si yín nígbà tí ẹ bá dé Ijipti. Ẹ óo di ẹni ègún, ẹni àríbẹ̀rù, ẹni ẹ̀gàn ati ẹni ẹ̀sín. Ẹ kò sì ní fojú kan ilẹ̀ yìí mọ́.’
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli wi, pe, Gẹgẹ bi emi ti dà ibinu mi ati irunu mi sori awọn olugbe Jerusalemu; bẹ̃ni emi o dà irunu mi le nyin lori, ẹnyin ti yio lọ si Egipti: ẹnyin o si di ẹni-ègun, ati ẹni-iyanu, ati ẹ̀gan, ati ẹ̀sin; ẹnyin kì yio si tun ri ibi yi mọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Báyìí ni ohun tí OLÚWA àwọn ọmọ ogun Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí: ‘Gẹ́gẹ́ bí èmi ti da ìbínú àti ìrunú síta sórí àwọn tí ó ń gbé ní Jérúsálẹ́mù, bẹ́ẹ̀ ni ìrunú mi yóò dà sita sórí yín, nígbà tí ẹ̀yin bá lọ sí Éjíbítì. Ẹ̀yin ó sì di ẹni ègún àti ẹní ẹ̀gàn àti ẹ̀sín, ẹ̀yin kì yóò sì rí ibí yìí mọ́.’