Jeremiah 42:2 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wọ́n wí fún un pé, “Nǹkan kan ni a fẹ́ bẹ̀ ọ́ fún, a sì fẹ́ kí o ṣe é fún wa: jọ̀wọ́, gbadura sí OLUWA Ọlọrun rẹ fún àwa ati gbogbo àwọn tí wọ́n ṣẹ́kù, nítorí pé a ti pọ̀ tẹ́lẹ̀ rí, ṣugbọn díẹ̀ ninu wa ni ó kù, bí ìwọ náà ti fi ojú ara rẹ rí i.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si sọ fun Jeremiah woli, pe, Awa bẹ ọ, jẹ ki ẹ̀bẹ wa ki o wá siwaju rẹ, ki o si gbadura fun wa si Oluwa Ọlọrun rẹ, ani fun gbogbo iyokù yi; (nitori lati inu ọ̀pọlọpọ, diẹ li awa kù, gẹgẹ bi oju rẹ ti ri wa:)
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Sí ọ̀dọ̀ Jeremáyà wòlíì náà, wọ́n sì sọ fún un pé, “Jọ̀wọ́ gbọ́ ẹ̀bẹ̀ wa, kí o sì gbàdúrà sí OLÚWA Ọlọ́run rẹ fún gbogbo ìyókù yìí. Nítorí gẹ́gẹ́ bi ìwọ ṣe rí i nísinsin yìí pé a pọ̀ níye nígbà kan rí; ṣùgbọ́n báyìí àwa díẹ̀ la sẹ́kù